Mojuba -- J-Sax Ft Yemisi Ogidan (Prod. by Harmonica)


J-SAX, one of the Nigeria fast rising Saxophonist, Worshiper Extraordinaire and Artiste has emerged on the gospel music scene for the release of his much-anticipated debut single “Mo Juba".

"MO JUBA" is an inspirational Worship Song by J-SAX Feat YEMISI OGIDAN.
With a melody in his heart, the Nigerian singer-songwriter testifies of God's unfailing love on this new record.

In his words, “The song “Mo Juba” came from the depth of my heart to appreciate God's faithfulness".
When you think there is no reason for you to give thanks to God
Think about gift of life
As for me "MO JUBA" oba to dami si ooo


CONTACT J-SAX VIA
IG:@iamjsax
Fb:J-Sax
YouTube :J-Sax
Nos:08033758894
Email: iamjsax@gmail.com

 
Lyrics 

MOJÚBÀ

(Instrumental)

Ìpè:
  Mo júbàà...mó o júbà rẹ
Mo júbà...ìbà fún ọlọ́run -ùn mi
 Ìdáhùn:
  Mo júbàà...mó o júbà rẹ
Mo júbà...ìbà fún ọlọ́run -ùn mi

(Instrumental)


Verse1.

Ọlọ́run alágbára, agbára tó so sánmọ̀ roó,

Ògbénú wúńdíá sọlá,
Òyígíyigì ọba,

Ọ̀rọ̀ tó ńgbé ọ̀rọ̀ ọ́ mìn,

Ọlọ́run ọkùnrin ogun

Ọ̀gbàmùgbámú ojúọ́run,
Tí kòó seé gbámú,

 *Ègbè* :
Mo júbà...ìbà fún ọlọ́run -ùn mi!

 Call: Ọba ọlọ́wọ́gbọgbọrọ....
(Res): ọlọ́wọ́gbọgbọrọ,

Call: Tí ńyọmọ rẹ̀ nínú ọ̀fìn....
(res) :àhaháaaaa

 Call: Amúni mámà sáré, isẹ́ ọwọ́rẹ ìyanu ni.....
(res): onísẹ̀ ìyanu

Call: Ọlọ́run àkìkìtán...
Res): àkìkìtán ooooo

Call: Ọlọ́run àyìnyìn tán...
Res: .Àyìnyìn tán ooo

Call:
Ọba tí kìí kú....(éhehè)
Res:
 ìbàfún ọlọ́run-ùn mí


 *call* : Ẹbámijúbà bàbá ooo,
 *res* :   ìbààà...ìbààà....ìbààà

Call:
Atẹ́ rẹrẹ rẹrẹ kárí ayé ò
Res:
....ìbààà...ìbààà....ìbààà

  Call:
Óta sánmọ̀, ólọ bẹẹrẹbẹ....
Res:
..ìbààà...ìbààà....ìbààà

 -call:
ó dá òkun ó lọ salulu.....
Res:
....ìbààà...ìbààà....ìbààà

Call:
Mo sèbà fólórí aiyé,
Res:
(ìbààà...ìbààà....ìbààà)

Call:
Ẹkùn ọkọ òkè, ọba aládé mímọ́ ooo,

 (ìbààà...ìbààà....ìbààà)

ọba tó fi mímọ́ bora,

mímọ́ mímọ́ mímọ́ mímọ́ ló yí tẹ rẹ̀ ká,

Ọlọ́run àgbàgbà mẹ́rìndelógún,

Ọba tójú rẹ dába òrùn,

 ìró ohùn rẹ̀ wá dàbí ìrò omi ......(ìbààà...ìbààà....ìbààà)

(instrumental)

Comments

Popular posts from this blog

UNIUYO Postgraduate Admission List for 2017/2018 Academic Session is Out

Block Double Logins v1.1 – Premium WordPress plugin